Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 147:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa nítorí ohun rereláti máa kọrin ìyìnsí Ọlọ́run wa,ó yẹ láti kọrin ìyìn síi.

2. Olúwa kọ́ Jérúsálẹ́mù;O ko àwọn Ísírẹ́lì tí a lé sọnù jọ.

3. Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bajẹ́ sànó sì di ọgbẹ́ wọn.

4. Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ó sì pe ọ̀kọ̀ọkan wọn ní orúkọ

5. Títóbi ní Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbáraòye Rẹ̀ kò sì ní òpin.

6. Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ó Rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

7. Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwafi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

8. Ó fi ìkuukù bo àwọ sánmọ̀ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayéó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè

9. Ó pèṣè oúnjẹ fún àwọn ẹrankoàti fún awọn ọmọ àdàbà ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

Ka pipe ipin Sáàmù 147