Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 146:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa,fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi

2. Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mièmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run,níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.

3. Ẹ má ṣe ní ìgbẹkẹ̀lé nínú àwọn ọmọ aládé,àní, ọmọ ènìyàn,lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

4. Ẹ̀mí Rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ Rẹ̀:Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:

5. Ìbùkún ni fún ẹni tíỌlọ́run Jákọ́bù ń ṣe ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀tí ìrètí Rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run Rẹ̀,

6. Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayéòkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn Olúwa, tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí láéláé

7. Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni láratí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)

8. Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran Olúwa, gbé àwọn tí a Rẹ̀ sílẹ̀ ga Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.

9. Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejòó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó síṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 146