Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 145:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ

16. Ìwọ sí ọwọ́ Rẹìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17. Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà Rẹ̀àti ìfẹ́ Rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.

18. Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

19. Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ṣẹ;ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

20. Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ síṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹnibúburú ní yóò parun.

21. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 145