Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 145:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Kí gbogbo ènìyàn le mọ isẹ́ agbára rẹ̀àti ola ńlá ìjọba Rẹ tí ó lógo.

13. Ìjọba Rẹ ìjọba ayérayé ni,àti ìjọba Rẹ wà ní gbogbo ìran-díran.

14. Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú róó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.

15. Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ

16. Ìwọ sí ọwọ́ Rẹìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17. Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà Rẹ̀àti ìfẹ́ Rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.

18. Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 145