Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 145:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;Èmi yóò yin orúkọ Rẹ̀ láé àti láéláé

2. Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Rẹ láé àti láéláé.

3. Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi Rẹ̀.

4. Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ Rẹ dé ìran mìíràn;wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára Rẹ

5. Wọn yóò máa sọ ìyìn ọlá ńlá Rẹ tí ó lógo,èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

6. Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára Rẹ tí ó ní ẹ̀rùèmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá Rẹ̀.

7. Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ìwà rere Rẹ àti orin ayọ̀ òdodo Rẹ.

8. Olore òfẹ́ ni Olúwa àti aláàánúó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀,

9. Olúwa dára sí ẹni gbogbo;ó ní àánú lóri ohungbogbo tí ó dá.

10. Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá niyóò máa yìn ọ́ Olúwa;àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí Rẹ.

11. Wọn yóò sọ ògo ìjọba Rẹwọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára Rẹ,

12. Kí gbogbo ènìyàn le mọ isẹ́ agbára rẹ̀àti ola ńlá ìjọba Rẹ tí ó lógo.

Ka pipe ipin Sáàmù 145