Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 144:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún-ún,tàbi ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa Rẹ̀?

4. Ènìyàn rí bí èmi;ọjọ́ Rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

5. Tẹ ọ̀run Rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí, rú èéfín.

6. Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀ta ká;ta ọfà Rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.

7. Na ọwọ́ Rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;gbà mí kí ó sì yọ mí nínú ewukúrò nínú omi ńlá:kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.

8. Ẹnu ẹni tí ó kún fún èkéẹni tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.

9. Èmi yóò kọ orin túntún sí ọỌlọ́run; lára ohun èlò orinolókùn mẹ́wàá èmi yóòkọ orin sí ọ

10. Sí ẹni tí ó fún àwọn ọba ní ìsẹ́gun,ẹni tí ó gba Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀lọ́wọ́ pípanirun.

11. Gbàmí kí ó sì yọ mí nínú ewukúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjìtí ẹnu wọn kún fún èké,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

12. Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igigbígbin tí ó dàgbà ni ìgba èwe wọn,àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilétí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

13. Àká wa yóò kúnpẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹàgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:

14. Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwokí ó má sí ìkọlù,kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,kí ó má síi igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

15. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náàtí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Ayọ̀ ni fún àwọntí ẹni ti Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.

Ka pipe ipin Sáàmù 144