Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 144:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,àti ìka mi fún ìjà.

2. Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó tẹ́rí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi

3. Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún-ún,tàbi ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa Rẹ̀?

4. Ènìyàn rí bí èmi;ọjọ́ Rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

5. Tẹ ọ̀run Rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí, rú èéfín.

6. Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀ta ká;ta ọfà Rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.

7. Na ọwọ́ Rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;gbà mí kí ó sì yọ mí nínú ewukúrò nínú omi ńlá:kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.

Ka pipe ipin Sáàmù 144