Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 141:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Jẹ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú Rẹ bí ẹbọtùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si okè rí bí i,ẹbọ àsàálẹ́.

3. Mú kí ìsṣ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:kí o sọ̀ máa pa ilẹ̀kùn ètè mi mọ́.

4. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburúmá sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ́ àdídùn wọn.

5. Jẹ́ kí olódodo lù mí: ìṣeun ni ó jẹ́:jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.Tí kì yóò fọ́ mí ní orí.Ṣíbẹ̀ àdúrà mi wá láí sí ìṣe àwọn olùṣe búburú

6. A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.

7. Egungun wa tàn kálẹ̀ ni ẹnuisà òkú, Bí ẹni tí ó ń tilẹ̀ tí ó sì ń la ilẹ̀,

8. Ṣùgbọ́n ojú mi wá ẹ, Olúwa, Ọlọ́run;nínú Rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe mú mi fún ikú.

9. Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tíwọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,kúrò nínú ìdẹkùn tí àwọnolùṣe búburú ti dẹ sílẹ̀.

10. Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,nígbà tí èmi kọjá láìléwu.

Ka pipe ipin Sáàmù 141