Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 140:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Olúwa, pa mí mọ́ kúròlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nìẹni tí ó ti pinnu Rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú

5. Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bá ọ̀nà;wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

6. Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7. Ọlọ́run Olúwa, agbára ìgbàlà mí,ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.

8. Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún ún;Má ṣe kún ọgbọ́n búburú Rẹ̀ lọ́wọ́;kí wọn kí ó máa baà gbé ara wọn ga. Sela

9. Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi kákiri ni,jẹ́ kí ìka ètè ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.

10. A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,sínú ọ̀gbun omi jínjìn,kí wọn kí ó má bà le dìde mọ́.

11. Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹṣẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

12. Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,yóò si ṣe ètò fun àwọn tálákà

Ka pipe ipin Sáàmù 140