Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 139:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,àwọn ọ̀tá Rẹ ń pe orúkọ Rẹ ní aṣán!

21. Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò korìíra àwọn tó korìíra Rẹ?Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?

22. Èmi korìíra wọn ní àkótán;èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.

23. Ọlọ́run, wádíì mi, kí ó sì mọ ọkàn mí;dán mi wò, kí ó sì mọ ìrò inú mi

24. Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburúkan bá wà nínú mi kí ó sìfi ẹṣẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

Ka pipe ipin Sáàmù 139