Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 139:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ Rẹ̀ yóò fà míọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì dì mí mú.

11. Bí mo bá wí pé, ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.

12. Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọdọ̀ Rẹ;ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjìbákan náà ní fún ọ.

13. Nítorí ìwọ ní ó dá ọkàn mi;ìwọ ní ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.

14. Èmi yóò yìn ọ nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àtitìyanu tìyanu ní a dá mi;ìyanu ní isẹ́ Rẹ; èyí nì níọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú

15. Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọdọ̀ Rẹ,nígbà tí á dá mi ní ìkọ̀kọ̀,tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà níìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.

16. Ojú Rẹ̀ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé:àti nínú ìwé Rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí,ní ojojumọ́ ni a ń dá wọn,nígbà tí ọ̀kan wọn kò tí i sí.

17. Ọlọ́run, ìrò inú Rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,iye wọn ti pọ̀ tó!

18. Èmi ibá kà wọ́n, wọ́n jù iyanrin lọ ní iye:nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ Rẹ̀ ṣíbẹ̀

19. Ọlọ́run ibá jẹ pa àwọn ènìyàn búburú ní tòótọ́;nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹ̀jẹ̀.

20. Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,àwọn ọ̀tá Rẹ ń pe orúkọ Rẹ ní aṣán!

21. Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò korìíra àwọn tó korìíra Rẹ?Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?

Ka pipe ipin Sáàmù 139