Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 139:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,ìwọ sì ti mọ̀ mí.

2. Ìwọ mọ̀ ìjòkòó mi àti ìdìde mi,ìwọ mọ̀ ìrò mi ní ọ̀nà jnijin réré.

3. Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi kán àti idùbúlẹ̀ mi,gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ.

4. Nítorí ti kò si ọ̀rọ kan ní ahọ́n mi,kíyèsíi, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátapáta.

5. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,ìwọ sì fi ọwọ́ Rẹ lé mi.

6. Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù;ó ga, èmi kò le mọ̀.

7. Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ní ọwọ́ ẹ̀mí Rẹ?Tàbí níbo ní èmi yóò sáré kúrò níwájú Rẹ?

Ka pipe ipin Sáàmù 139