Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 139:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,ìwọ sì ti mọ̀ mí.

2. Ìwọ mọ̀ ìjòkòó mi àti ìdìde mi,ìwọ mọ̀ ìrò mi ní ọ̀nà jnijin réré.

3. Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi kán àti idùbúlẹ̀ mi,gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ.

4. Nítorí ti kò si ọ̀rọ kan ní ahọ́n mi,kíyèsíi, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátapáta.

5. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,ìwọ sì fi ọwọ́ Rẹ lé mi.

6. Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù;ó ga, èmi kò le mọ̀.

7. Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ní ọwọ́ ẹ̀mí Rẹ?Tàbí níbo ní èmi yóò sáré kúrò níwájú Rẹ?

8. Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀.

9. Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin òkun;

10. Àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ Rẹ̀ yóò fà míọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì dì mí mú.

11. Bí mo bá wí pé, ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.

12. Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọdọ̀ Rẹ;ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjìbákan náà ní fún ọ.

Ka pipe ipin Sáàmù 139