Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 135:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀,tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.

11. Síónì, ọba àwọn ará Ámorì, àti Ógù,ọba Báṣánì, àti gbogbo ìjọba Kénánì:

12. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,ìní fún Ísírẹ́lì, ènìyàn Rẹ̀.

13. Olúwa orúkọ Rẹ dúró láéláé;ìrántí Rẹ Olúwa, láti ìran-díran.

14. Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀,yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

15. Sílífà Òun wúrà ní èrè àwọn aláìkọlà,iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn.

16. Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọ́n kò sọ̀rọ;wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

17. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́ràn;bẹ́ẹ̀ ni kò si èèmí kan ní ẹnu wọn

18. Àwọn tí ó ṣe wọn dàbí wọn:bẹ́ẹ̀ sì ní olúkùlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé wọn.

19. Ẹ̀yin ara ilé Ísírẹ́lì, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,ẹ̀yin ará ilé Árónì, fi ìbùkún fún Olúwa.

20. Ẹ̀yin ará ilé Léfì, fi ìbùkún fún Olúwa;ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.

21. Olùbùkún ní Olúwa, láti Síónì wá,tí ń gbé Jérúsálẹ́mù. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 135