Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 135:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ yìn Olúwa, ẹ yìn orúkọ Olúwa;Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.

2. Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.

3. Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ̀; ní torí tí ó dùn.

4. Nítorí tí Olúwa ti yàn Jákọ́bù fún ara Rẹ̀;àní Ísírẹ́lì fún ìṣúra ààyò Rẹ̀.

5. Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.

6. Ohunkóhun tí ó wu Olúwa, Òun ní iṣe ní ọ̀run,àti ní ayé, ní òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.

7. Ó mú ìkuku góke láti òpin ilẹ̀ wá:ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjo:ó ń mú afẹ́fé ti inú ilẹ̀ ìṣúra Rẹ̀ wá.

8. Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Éjíbítì,àti tí ènìyàn àti ti ẹranko.

9. Ẹni tí ó rán àmì àti iṣẹ ìyanu sí àrin Rẹ̀,ìwọ Éjíbítì, sí ara Fáráò,àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ gbogbo.

10. Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀,tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.

11. Síónì, ọba àwọn ará Ámorì, àti Ógù,ọba Báṣánì, àti gbogbo ìjọba Kénánì:

12. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,ìní fún Ísírẹ́lì, ènìyàn Rẹ̀.

13. Olúwa orúkọ Rẹ dúró láéláé;ìrántí Rẹ Olúwa, láti ìran-díran.

14. Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀,yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

15. Sílífà Òun wúrà ní èrè àwọn aláìkọlà,iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn.

16. Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọ́n kò sọ̀rọ;wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

17. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́ràn;bẹ́ẹ̀ ni kò si èèmí kan ní ẹnu wọn

18. Àwọn tí ó ṣe wọn dàbí wọn:bẹ́ẹ̀ sì ní olúkùlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé wọn.

19. Ẹ̀yin ara ilé Ísírẹ́lì, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,ẹ̀yin ará ilé Árónì, fi ìbùkún fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 135