Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 132:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí tí Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀Má ṣe yí ojú ẹni-òróró Rẹ padà.

11. Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dáfídì:Òun kí yóò yípadà kúrò nínú Rẹ̀,nínú irú ọmọ inú Rẹ ní èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ Rẹ.

12. Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókoo lórí ìtẹ́ Rẹ láéláé.

13. Nítorí tí Olúwa ti yan Síónì:ó ti fẹ́ẹ fún ibùjókòó Rẹ̀.

14. Èyí ní ibi ìsinmi mí láéláé:níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:nítorí tí mo fẹ́ ẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 132