Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 130:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Láti inú ibú wá níèmi ń képè ọ Olúwa

2. Olúwa, gbóhùn mi,jẹ́ kí etí Rẹ̀ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

3. Olúwa, ìbáṣe pé kí ìwọ kí o máa ṣàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tà ni ìbá dúró.

4. Nítorí ìdàríjìn wà lọ́dọ̀ Rẹ,kí a lè máa bẹ̀rù Rẹ.

5. Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,àti nínú ọ̀rọ̀ Rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí

6. Ọkàn mi dúró de Olúwa,ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,àní ju àwọn ti ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

7. Ísírẹ́lì, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáńdè wà.

8. Òun ó sì dá Ísírẹ́lì ní ìdèkúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ gbogbo.

Ka pipe ipin Sáàmù 130