Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 129:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:wọ́n sì là aporo wọn gígùn.

4. Olódodo ní Olúwa:ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.

5. Kí gbogbo àwọn tí ó korìíra Síónì kí ó dààmú,kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.

6. Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀tí ó gbẹ dànù kí o tó dàgbà sókè:

7. Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ Rẹ̀:bẹ́ẹ̀ ní ẹni tí ń di ìtì, kó kún apá Rẹ̀.

8. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kó wí pé,ìbùkún Olúwa kí o pẹ̀lú yín:àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 129