1. Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà Rẹ̀
2. Nítorí tí ìwọ yóò jẹ isẹ́ ọwọ́ Rẹìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
3. Obìnrin Rẹ yóò dà bí àjàrà rereeléso púpọ̀ ní àárin ilé Rẹ;àwọn ọmọ Rẹ yóò dà bí igi olífì tí ó yí tábìlì Rẹ ká.
4. Kíyèsíi pé, bẹ́ẹ̀ ni a o bù síi fún ọkùnrin náà,tí o bẹ̀rù Olúwa.