Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 126:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Olúwa mú ìkòlọ Síónì padà,àwa dàbí ẹni tí o ń lá àlá.

2. Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,àti ahọ́n wa kọ orin;nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn aláìkọlà pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.

3. Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;nítorí náà àwa ń yọ̀.

4. Olúwa mú ìkólọ wa padà,bí ìṣàn omi ní gúsù.

5. Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìnyóò fi ayọ̀ ka.

6. Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,lóòtọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,yóò sì ru ìtí Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 126