Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 124:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìba má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”ni kí Ísírẹ́lì kí ó máa wí nísinsìn yìí;

2. “Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:

3. Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láàyènígbà tí ìbínú wọn ru sí wá

4. Nígbà náà ni omiwọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀

5. Nígbà náà ni agbéragaomi ìbá borí ọkàn wa.

6. Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́nbí ohun ọdẹ fún eyín wọn.

7. Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;okùn já àwa sì yọ.

8. Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Ka pipe ipin Sáàmù 124