Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 121:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá

2. Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wáẸni tí ó dá ọ̀run òun ayé

3. Òun kì yóò jẹ́ kí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ kí ó yẹ̀;ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

4. Kíyèsí, ẹni tí ń pa Ísírẹ́lì mọ́,kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

5. Olúwa ni olùpamọ́ Rẹ; Olúwa ní òjìji Rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ

6. Oòrùn kì yóò pa ọ ní ìgbà ọ̀sántàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Ka pipe ipin Sáàmù 121