Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:99-113 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

99. Èmi ní iyè ińu ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin Rẹ.

100. Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,nítorí mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ.

101. Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibinítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ Rẹ.

102. Èmi kò yà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ìwọ fún rarẹ̀ ni ó kọ́ mi.

103. Báwo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!

104. Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ Rẹ;nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

105. Ọ̀rọ̀ Rẹ ni ó ṣe fítílà sí ẹṣẹ̀ miàti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi

106. Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọnwí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo Rẹ.

107. A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Rẹ

108. Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,kí o sì kọ́ mi ní òfin Rẹ̀.

109. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ minígbà gbogbo,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

110. Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,ṣùgbọ́n èmi kò sìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ.

111. Òfin Rẹ ni ogún mi láéláé;àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.

112. Ọkàn mi ti lé pípa òfin Rẹ mọ́láé dé òpin.

113. Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì,ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119