Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:91-102 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

91. Òfin Rẹ dúró di ònínítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.

92. Bí òfin Rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.

93. Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ láé,nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́

94. Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹèmi ti wá ẹ̀kọ́ Rẹ.

95. Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsí ẹ̀rí Rẹ.

96. Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;ṣùgbọ́n àṣẹ Rẹ aláìlópin ni.

97. Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin Rẹ tó!Èmi ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.

98. Àṣẹ Rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀ta mi lọ,nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.

99. Èmi ní iyè ińu ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin Rẹ.

100. Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,nítorí mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ.

101. Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibinítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ Rẹ.

102. Èmi kò yà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ìwọ fún rarẹ̀ ni ó kọ́ mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 119