Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:81-94 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

81. Ọkàn mi ń fojú sọ́nà nítorí ìgbàlà Rẹ,ṣùgbọ́n èmi tí mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

82. Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wí wo ìpinu Rẹ;èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”

83. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí àmọ́ wáìnì nínú èéfín,èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

84. Báwo ni ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọntí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?

85. Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,tí ó lòdì sí òfin Rẹ.

86. Gbogbo àsẹ Rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:rànmílọ́wọ́, nítorí ènìyànń ṣe inúnibíni sí mi láì nídìí.

87. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,ṣùgbọ́n èmi kò kọ̀ ẹ̀kọ́ Rẹ.

88. Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ,èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu Rẹ̀ gbọ́.

89. Ọ̀rọ̀ Rẹ, Olúwa, títí láé ni;ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run

90. Òtítọ́ Rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.

91. Òfin Rẹ dúró di ònínítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.

92. Bí òfin Rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.

93. Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ láé,nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́

94. Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹèmi ti wá ẹ̀kọ́ Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119