Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:76-85 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

76. Kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ.

77. Jẹ́ kí àánú Rẹ kí ó tọ̀ò mí wá kí èmi kí ó lè yè,nítorí òfin Rẹ̀ jẹ́ ìdùnnú mi.

78. Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraganítorí wọn pamí lára láìnídìíṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

79. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ yí padà sí mí,àwọn tí ó ní òye òfin Rẹ.

80. Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin Rẹ,kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

81. Ọkàn mi ń fojú sọ́nà nítorí ìgbàlà Rẹ,ṣùgbọ́n èmi tí mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

82. Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wí wo ìpinu Rẹ;èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”

83. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí àmọ́ wáìnì nínú èéfín,èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

84. Báwo ni ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọntí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?

85. Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,tí ó lòdì sí òfin Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119