Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:72-80 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

72. Òfin tí ó jáde láti ẹnu Rẹ ju iyebíye sí mi lọó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ

73. Ọwọ́ Rẹ ní ó dá mi tí ó sì mọ mí;fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ Rẹ.

74. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ máa yọ̀nígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

75. Èmi mọ̀, Olúwa, nítorí òfin Rẹ òdodo ni,àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.

76. Kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ.

77. Jẹ́ kí àánú Rẹ kí ó tọ̀ò mí wá kí èmi kí ó lè yè,nítorí òfin Rẹ̀ jẹ́ ìdùnnú mi.

78. Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraganítorí wọn pamí lára láìnídìíṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

79. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ yí padà sí mí,àwọn tí ó ní òye òfin Rẹ.

80. Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin Rẹ,kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

Ka pipe ipin Sáàmù 119