Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:67-77 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

67. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti sìnà,ṣùgbọ́n ni ìsinsinyí èmi gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

68. Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;kọ́ mi ní ìlànà Rẹ.

69. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti Rẹ̀ mí pẹ̀lú èkéèmi pa ẹ̀kọ́ Rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

70. Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin Rẹ.

71. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójúnítorí kí èmi lè kọ́ òfin Rẹ.

72. Òfin tí ó jáde láti ẹnu Rẹ ju iyebíye sí mi lọó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ

73. Ọwọ́ Rẹ ní ó dá mi tí ó sì mọ mí;fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ Rẹ.

74. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ máa yọ̀nígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

75. Èmi mọ̀, Olúwa, nítorí òfin Rẹ òdodo ni,àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.

76. Kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ.

77. Jẹ́ kí àánú Rẹ kí ó tọ̀ò mí wá kí èmi kí ó lè yè,nítorí òfin Rẹ̀ jẹ́ ìdùnnú mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 119