Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:58-63 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

58. Èmi ti wá ojú Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:fún mi ní oore ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

59. Èmi ti kíyèsí ọ̀nà mièmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin Rẹ.

60. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́raláti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ.

61. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

62. Ní àárin ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọnítorí òfin òdodo Rẹ̀.

63. Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ,sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 119