Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:55-68 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

55. Ní òru èmi rántí orúkọ Rẹ, Olúwa,èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́

56. nitori ti mogba ẹ̀kọ́ Rẹ gbọ́.

57. Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

58. Èmi ti wá ojú Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:fún mi ní oore ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

59. Èmi ti kíyèsí ọ̀nà mièmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin Rẹ.

60. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́raláti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ.

61. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

62. Ní àárin ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọnítorí òfin òdodo Rẹ̀.

63. Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ,sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

64. Ayé kún fún ìfẹ́ Rẹ OlúwaKọ́ mi ní òfin Rẹ.

65. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹgẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ, Olúwa.

66. Kọ́ mi ni ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ Rẹ.

67. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti sìnà,ṣùgbọ́n ni ìsinsinyí èmi gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

68. Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;kọ́ mi ní ìlànà Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119