Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:33-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ Rẹ;nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́èmi yóò sì máa kíyèsíi pẹ̀lú ọkàn mi.

35. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ hàn mí,nítorí nínú Rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

36. Yí ọkàn mi padà sí òfin Rẹ̀kí ó má ṣe sí ojú kòkòrò mọ́.

37. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:pa ayé mí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

38. Mú ìlérí Rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí òfin Rẹ dára.

39. Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rùni torí tí idájọ́ Rẹ dára.

40. Kíyèsíi ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ Rẹ!Pa ayé mí mọ́ nínú òdodo Rẹ.

41. Jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,ìgbàlà Rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ;

42. Nígbà náà ni èmi yóò dáẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ Rẹ.

43. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu minítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ Rẹ

44. Èmi yóò máa gbọ́ràn sí òfin Rẹ nígbà gbogboláé àti láéláé.

45. Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jáde.

Ka pipe ipin Sáàmù 119