Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:20-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nànítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo.

21. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn-úntí ó sìnà kúrò nínú àṣẹ Rẹ.

22. Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,nítorí èmi pa òfin Rẹ mọ́.

23. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́nń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ.

24. Òfin Rẹ ni dídùn inú mi;àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi.

25. Èmi tẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ sínú erùpẹ̀;pa ayé mi mọ́ sí ipa ọ̀rọ̀ Rẹ.

26. Èmi tún ọ̀nà mi síròṣ ìwọ sì dá mí lóhùn;kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

27. Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀:nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

28. Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

29. Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tànfún mi ní oore ọ̀fẹ́ nípa òfin Rẹ.

30. Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin Rẹ.

31. Èmi yára di òfin Rẹ mú. Olúwamá ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

32. Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ,nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

33. kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ Rẹ;nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́èmi yóò sì máa kíyèsíi pẹ̀lú ọkàn mi.

35. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ hàn mí,nítorí nínú Rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

36. Yí ọkàn mi padà sí òfin Rẹ̀kí ó má ṣe sí ojú kòkòrò mọ́.

37. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:pa ayé mí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

38. Mú ìlérí Rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí òfin Rẹ dára.

Ka pipe ipin Sáàmù 119