Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:159-176 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

159. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ;pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ.

160. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ;gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni.

161. Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

162. Èmi yọ̀ nínú ìpinnu Rẹbí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.

163. Èmi kórìíra mo sì gba èké ṣíṣeṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin Rẹ.

164. Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́nítorí òfin òdodo Rẹ.

165. Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin Rẹ,kò sì si ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166. Èmi yóò dúró de ìgbàlà Rẹ, Olúwa,èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ Rẹ.

167. Èmi gba òfin Rẹ gbọ́,nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀ púpọ̀

168. Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ Rẹ àti òfin Rẹ,nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.

169. Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú Rẹ, Olúwa;fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

170. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú Rẹ;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

171. Ètè mi yóò sọ ìyin jáde,nítorí ìwọ kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ.

172. Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ Rẹ,nítorí gbogbo àṣẹ Rẹ jẹ́ òdodo.

173. Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ ṣetan láti rànmílọ́wọ́,nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ Rẹ.

174. Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà Rẹ, Olúwa,àti òfin Rẹ jẹ́ dídùn inú mi.

175. Jẹ́ kí èmi wà láàyè ki èmi lè yìn ọ́,kí o sì jẹ́ kí òfin Rẹ mú mi dúró.

176. Èmí ti sìnà bí àgùntàn tí ósọnùú wá ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119