Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:152-167 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

152. Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹtí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

153. Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

154. Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

155. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156. Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

157. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ.

158. Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́.

159. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ;pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ.

160. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ;gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni.

161. Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

162. Èmi yọ̀ nínú ìpinnu Rẹbí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.

163. Èmi kórìíra mo sì gba èké ṣíṣeṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin Rẹ.

164. Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́nítorí òfin òdodo Rẹ.

165. Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin Rẹ,kò sì si ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166. Èmi yóò dúró de ìgbàlà Rẹ, Olúwa,èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ Rẹ.

167. Èmi gba òfin Rẹ gbọ́,nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀ púpọ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 119