Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:151-156 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

151. Ṣíbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,àti gbogbo àsẹ Rẹ jẹ́ òtítọ́.

152. Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹtí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

153. Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

154. Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

155. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156. Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119