Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:144-153 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

144. Òfin Rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;fún mi ní òyé kí èmi lè yè.

145. èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:dámi lóhùn Olúwa,èmi yóò sì gbọ́ràn sí àsẹ Rẹ.

146. Èmi kígbe pè ọ́; gbà míèmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́.

147. Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìràn lọ́wọ́;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

148. Ojú mi ṣááju ìsọ́ òru,nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ r.

149. Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ:pa ayé mí mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

150. Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòòsí,ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin Rẹ.

151. Ṣíbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,àti gbogbo àsẹ Rẹ jẹ́ òtítọ́.

152. Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹtí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

153. Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 119