Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èmi yọ̀ nínú títẹ̀lé òrin Rẹbí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọlá ńlá.

15. Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà Rẹèmi sì kíyèsí ọ̀nà Rẹ

16. Inú mi dùn sí àṣẹ Rẹ;èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà Rẹ.

17. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ, èmi yóò sì wà láàyè;èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

18. La ojú mi kí èmi lè ríran ríohun ìyanu tí ó wà nínú òfin Rẹ.

19. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;Má ṣe pa àṣẹ Rẹ mọ́ fún mi.

20. Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nànítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Sáàmù 119