Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:116-126 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

116. Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ,kí èmi kí ó lè yèMá sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.

117. Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin Rẹ.

118. Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.

119. Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọyọ kúrò bí i ìdàrọ́;nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀.

120. Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀:èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ

121. Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.

122. Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú:má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

123. Ojú mi kùnà, fún wí wo ìgbàlà Rẹ,fún wíwo ìpinu òdodo Rẹ.

124. Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹkí o sì kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

125. Èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ; ẹ fún mi ní òyekí èmi lè ní òye òfin Rẹ

126. Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;nítorí òfin Rẹ ti fọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 119