Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 119:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́sẹ̀,ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,

2. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin Rẹ̀ mọ́tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

3. Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;wọ́n rìn ní ọ̀nà Rẹ̀.

4. Ìwọ ti la ìlànà Rẹ̀ sílẹ̀kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.

5. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣinláti máa pa òfin Rẹ̀ mọ́!

6. Nígbà náà, ojú kò ní tì mínígbà tí mo bá ń kíyèsí àṣẹ Rẹ̀ gbogbo.

7. Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣinbí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo Rẹ̀.

8. Èmi yóò gbọ́ràn sí asẹ Rẹ̀:Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátapáta.

Ka pipe ipin Sáàmù 119