Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 118:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Olúwa bá mi wí gidigidi,ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19. Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òdodo fún mi:èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.

20. Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwaibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.

21. Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dámi lóhùn;ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ni ó di pàtàkì òkúta igun ilé;

Ka pipe ipin Sáàmù 118