Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 118:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Wọn yí mi ká kiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù

12. Wọn gbá yìnìn yí mí ká bí oyin,ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.

13. Ìwọ tì mi gidigidi kí ń lè subú,ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.

14. Olúwa ni agbára àti orin mi;ó si di ìgbàlà mi.

15. Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:“ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!

16. Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbé ga;ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”

17. Èmi kì yóò kú ṣùgbọ́n èmi yóò yè,èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.

18. Olúwa bá mi wí gidigidi,ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19. Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òdodo fún mi:èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 118