Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 116:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà náà ni mo ké pé orúkọ Olúwa:“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi”

5. Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́ ó sì ní òdodo;Ọlọ́run wa kún fún àánú.

6. Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

7. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi Rẹ,nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

8. Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mikúrò lọ́wọ́ ikú,ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,

9. Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwaní ilẹ̀ alààyè.

10. Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,“èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.

11. Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé“Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12. Kí ni èmi yóò san fún Olúwanítorí gbogbo rere Rẹ̀ sí mí?

13. Èmi yóò gbé aago ìgbàlà sókèèmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.

14. Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwaní ojú àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Iyebíye ní ojú Olúwaàti ikú àwọn ẹni mímọ́ Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 116