Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 116:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé“Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12. Kí ni èmi yóò san fún Olúwanítorí gbogbo rere Rẹ̀ sí mí?

13. Èmi yóò gbé aago ìgbàlà sókèèmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.

14. Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwaní ojú àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Iyebíye ní ojú Olúwaàti ikú àwọn ẹni mímọ́ Rẹ̀.

16. Olúwa, ní tòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ ni mo jẹ́;èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ, ọmọ ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ;ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17. Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọèmi yóò sì képe orúkọ Olúwa

18. Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwaní ojú gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀,

19. Nínú àgbàlá ilé Olúwani àárin Rẹ̀, ìwọ Jérúsálẹ́mù.Ẹ yin Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 116