Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 116:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.

2. Nítorí ó yí etí Rẹ̀ padà sí mi,èmi yóò máa, pè é ní wọ̀n ìgbà tí mo wà láàyé.

3. Òkun ikú yí mi ka,ìrora isà òkú wá sórí mi;ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.

4. Nígbà náà ni mo ké pé orúkọ Olúwa:“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi”

5. Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́ ó sì ní òdodo;Ọlọ́run wa kún fún àánú.

6. Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

7. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi Rẹ,nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

8. Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mikúrò lọ́wọ́ ikú,ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,

9. Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwaní ilẹ̀ alààyè.

Ka pipe ipin Sáàmù 116