Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 113:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ máa yin Olúwa, yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,ẹ yin orúkọ Olúwa.

2. Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa látiìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

3. Láti ìlà òòrun títí dé ìwọ Rẹ̀orúkọ Olúwa ni kí á máa yìn.

4. Olúwa ga lórí gbogbo ayé,àti ògo Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.

5. Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,tí ó gbé ní ibi gíga.

6. Tí ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ láti wòòun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

7. Ó gbé òtòsì dìde láti inú erùpẹ̀, àti péó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.

8. Kí ó le mú-un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ aládéàní pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé àwọn ènìyàn Rẹ̀.

9. Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ Rẹ̀.Ẹ yin Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 113