Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 112:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ìbùkún ni fún Ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,tí ó ní inúdídùn ńlá sí àwọn òfin Rẹ̀.

2. Iru ọmọ Rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:ìran àwọn olóòótọ́ ni a ó bùkún fún

3. Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé Rẹ̀:òdodo Rẹ̀ sì dúró láé.

4. Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ni òkùnkùn:olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.

5. Ọkùnrin rere fí ojú rere hàn, a sì wín ni,ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ Rẹ̀.

6. Dájúdájú kì yóò le yí ni ìpo padà láéláé:olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí ní ayérayé.

7. Òun kì yóò bèèrè ìyìn búburú:ọkàn Rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

8. Ó ti mú ọkàn Rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bàá,títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkan Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 112