Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 108:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Èmi ó yìn ọ, Ọlọ́run nínú àwọn orílẹ̀ èdèèmi o kọrin Rẹ nínú àwọn ènìyàn

4. Nítorí tí o tóbi ní àánú Rẹju àwọn ọ̀run lọàti òdodo Rẹ dé àwọ̀sánmọ̀

5. Gbé ara Rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,àti ògo Rẹ lórí gbogbo ayé.

6. Gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́, pẹ̀lúọwọ́ ọ̀tún Rẹ, se igbala,ki o si da mi lóhùn

7. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ níbi mímọ́“Ní ìsẹ́gun ní èmi ó ké Sékémùèmi yóò sì wọ́n ibi gíga Sukobù

8. Gílíádì ni tèmi, Mánásè ni tèmiÉfuraimù ní ìbòrí miJúdà ní olófin mi

9. Móábù si ni ìkòkò ìwàsẹ̀ milórí Édómù ní èmi ó bọ́ bàtà mi sílórí òkè Fílísitínì ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”

10. Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódiTa ni yóò sìn mi wá sí Édómù

11. Ìwọ Ọlọ́run há kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.

12. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njúnítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni

13. Nípaṣẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akinnítorí oun ó tẹ àwọn ọ̀ta wa mọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 108