Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 108:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣinèmi ó máa kọrin, èmi o máa fi ọkàn mi kọrin

2. Jí ohun èlò orin àti háápùèmi ó jí ní kùtùkùtù

3. Èmi ó yìn ọ, Ọlọ́run nínú àwọn orílẹ̀ èdèèmi o kọrin Rẹ nínú àwọn ènìyàn

4. Nítorí tí o tóbi ní àánú Rẹju àwọn ọ̀run lọàti òdodo Rẹ dé àwọ̀sánmọ̀

5. Gbé ara Rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,àti ògo Rẹ lórí gbogbo ayé.

6. Gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́, pẹ̀lúọwọ́ ọ̀tún Rẹ, se igbala,ki o si da mi lóhùn

Ka pipe ipin Sáàmù 108