Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 107:22-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ̀.

23. Àwọn ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun nínú ọkọ̀ojú omi, wọn jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.

24. Wọn ri iṣẹ́ Olúwa,àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ nínú ibú

25. Nítorí tí ó pasẹ, ó sì mú ìjì fẹ́tí ó gbé ríru Rẹ̀ sókè.

26. Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọn sìtún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:nítorí ìpọ́njú ọkan wọn di omi

27. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:ọgbọ́n wọn sì dé òpin.

28. Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókèsí Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.

29. Ó sọ ìjì di ìdákẹ́-rọ́rọ́bẹ́ẹ̀ ní rirú omi Rẹ̀ duro jẹ́ẹ́;

30. Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,

31. Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

32. Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárin àwọn ènìyànkí wọn kí ó sì yín ín ní ìjọ àwọn àgbà.

33. Ó sọ odò di ihà,àti orisun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.

34. Ilẹ̀ eleso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú Rẹ̀;

35. O sọ ihà di adágún omi àtiilẹ̀ gbígbẹ di oríṣun omi

36. Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,wọ́n sì pìlẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé

37. Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàràtí yóò ma so èso tí ó dára;

Ka pipe ipin Sáàmù 107