Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 107:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé.

2. Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí bayí, àwọnẹni tí ó ràpadà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

3. Àwọn tí ó kó jọ láti ilẹ̀ wọ̀nnìláti ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn,láti àríwá àti òkun wá.

4. Wọn ń rìn káàkiri ni ihà ni ibi tí ọ̀nà kò sí,wọn kòrí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tíwọn ó máa gbé

5. Ebi ń pa wọn, òùngbẹ gbẹ wọn,ó sì Rẹ̀ ọkàn wọn nínú wọn.

6. Ní ìgbà náà wọn kígbe sókèsí Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn

7. Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlútí wọ́n lè máa gbé

8. Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ìyanu Rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

9. Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́runó sì fi ire fún ọkàn tí ebi ń pa.

10. Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,a dè wọ́n ni ìrora àti ní irin,

11. Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀Ọlọ́run, wọn kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá ògo,

12. Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀;wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tíyóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

13. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

14. Ó mú wọn jáde kúrò nínúòkùnkùn àti òjìji ikú,ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

15. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

16. Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nìó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì.

Ka pipe ipin Sáàmù 107